Add parallel Print Page Options

Jesu rìn lórí omi

45 (A)Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ lẹ́yìn èyí, Jesu pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti padà sínú ọkọ̀ kí wọn sì ṣáájú rékọjá sí Betisaida. Níbẹ̀ ni òun yóò ti wà pẹ̀lú wọn láìpẹ́. Nítorí òun fúnra a rẹ̀ yóò dúró sẹ́yìn láti rí i pé àwọn ènìyàn túká lọ ilé wọn. 46 Lẹ́yìn náà, ó lọ sórí òkè láti lọ gbàdúrà.

Read full chapter

15 (A)Nígbà tí Jesu sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jẹ ọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan.

Jesu rin lórí omi

16 (B)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun. 17 Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá Òkun lọ sí Kapernaumu. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jesu kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn.

Read full chapter