Add parallel Print Page Options

47 Nígbà tí ó di alẹ́, ọkọ̀ wà láàrín Òkun, òun nìkan sì wà lórí ilẹ̀. 48 (A)Ó rí i wí pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà nínú wàhálà púpọ̀ ní wíwa ọkọ̀ náà nítorí ti ìjì líle ṣe ọwọ́ òdì sí wọn, nígbà tí ó sì dì ìwọ̀n ìṣọ́ kẹrin òru, ó tọ̀ wọ́n wá, ó ń rìn lórí omi Òkun, òun sì fẹ́ ré wọn kọjá, 49 ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí i tí ó ń rìn, wọ́n rò pé iwin ni. Wọ́n sì kígbe sókè lóhùn rara, 50 (B)nítorí gbogbo wọn ni ó rí i, tí ẹ̀rù sì bà wọ́n.

Ṣùgbọ́n òun sọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé, “Ẹ mú ọkàn le! Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù.” 51 Nígbà náà ni ó gòkè sínú ọkọ̀ pẹ̀lú wọn, ìjì líle náà sì dáwọ́ dúró. Ẹ̀rù sì bà wọ́n rékọjá gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n. 52 (C)Wọn kò sá tó ni òye iṣẹ́ ìyanu ti ìṣù àkàrà, nítorí ti ọkàn wọn yigbì.

Read full chapter

Jesu rin lórí omi

16 (A)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun. 17 Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá Òkun lọ sí Kapernaumu. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jesu kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn. 18 Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúùfù líle tí ń fẹ́. 19 Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jesu ń rìn lórí Òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n. 20 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.” 21 Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkan náà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń lọ.

Read full chapter