Add parallel Print Page Options

Jesu rán àwọn méjìlá jáde

10 (A)Jesu sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí ọ̀dọ̀; ó fún wọn ní àṣẹ láti lé ẹ̀mí àìmọ́ jáde àti láti ṣe ìwòsàn ààrùn àti àìsàn gbogbo.

Read full chapter

(A)Àwọn méjèèjìlá wọ̀nyí ni Jesu ran, ó sì pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe lọ sì ọ̀nà àwọn kèfèrí, ẹ má ṣe wọ̀ ìlú àwọn ará Samaria

Read full chapter

Bí ẹ̀yin ti ń lọ, ẹ máa wàásù yìí wí pé: ‘Ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ máa ṣe ìwòsàn fún àwọn aláìsàn, ẹ si jí àwọn òkú dìde, ẹ sọ àwọn adẹ́tẹ̀ di mímọ́, kí ẹ sì máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà á, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fi fún ni.

“Ẹ má ṣe mú wúrà tàbí fàdákà tàbí idẹ sínú àpò ìgbànú yín; 10 Ẹ má ṣe mú àpò fún ìrìnàjò yín, kí ẹ má ṣe mú ẹ̀wù méjì, tàbí bàtà, tàbí ọ̀pá; oúnjẹ oníṣẹ́ yẹ fún un. 11 Ìlúkílùú tàbí ìletòkíletò tí ẹ̀yin bá wọ̀, ẹ wá ẹni ti ó bá yẹ níbẹ̀ rí, níbẹ̀ ni kí ẹ sì gbé nínú ilé rẹ̀ títí tí ẹ̀yin yóò fi kúrò níbẹ̀.

Read full chapter

Jesu rán ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá lọ wàásù

(A)Ó sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn. Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe mú nǹkan lọ́wọ́ fún àjò yín, ọ̀pá, tàbí àpò tàbí àkàrà, tàbí owó: bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má sì ṣe ní ẹ̀wù méjì. Ní ilékílé tí ẹ̀yin bá sì wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin gbé, láti ibẹ̀ ni kí ẹ̀yin sì ti jáde. (B)Iye àwọn tí kò bá si gbà yín, nígbà tí ẹ̀yin bá jáde kúrò ní ìlú náà, ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín fún ẹ̀rí sí wọn.”

Read full chapter