Add parallel Print Page Options

21 Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Koraṣini, ègbé ni fún ìwọ Betisaida! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú yín ní a ṣe ni Tire àti Sidoni, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà ti pẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú. 22 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, yóò sàn fún Tire àti Sidoni ní ọjọ́ ìdájọ́ jù fún yín. 23 Àti ìwọ Kapernaumu, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run? Rárá, a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sodomu, òun ìbá wà títí di òní.

Read full chapter

24 (A)(B) “Ègbé ni fún ẹ̀yin ọlọ́rọ̀
    nítorí ẹ ti gba ìtùnú yín.
25 Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ó yó,
    nítorí ebi yóò pa yín,
Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ń rẹ́rìn-ín nísinsin yìí,
    nítorí tí ẹ̀yin ó ṣọ̀fọ̀, ẹ̀yin ó sì sọkún.
26 Ègbé ni fún yín, nígbà tí gbogbo ènìyàn bá ń sọ̀rọ̀ yín ní rere,
    nítorí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn baba wọn ṣe sí àwọn wòlíì èké.

Read full chapter