Add parallel Print Page Options

Òwe afúnrúgbìn

13 (A)Ní ọjọ́ kan náà, Jesu kúrò ní ilé, ó jókòó sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, ó jókòó, gbogbo ènìyàn sì dúró létí Òkun. Nígbà náà ni ó fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe bá wọn sọ̀rọ̀, wí pé: “Àgbẹ̀ kan jáde lọ gbin irúgbìn sínú oko rẹ̀. Bí ó sì ti gbin irúgbìn náà, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, àwọn ẹyẹ sì wá, wọ́n sì jẹ ẹ́. Díẹ̀ bọ́ sórí ilẹ̀ orí àpáta, níbi ti kò sí erùpẹ̀ púpọ̀. Àwọn irúgbìn náà sì dàgbàsókè kíákíá, nítorí erùpẹ̀ kò pọ̀ lórí wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí oòrùn gòkè, oòrùn gbígbóná jó wọn, gbogbo wọn sì rọ, wọ́n kú nítorí wọn kò ni gbòǹgbò. Àwọn irúgbìn mìíràn bọ́ sí àárín ẹ̀gún, ẹ̀gún sì dàgbà, ó sì fún wọn pa. Ṣùgbọ́n díẹ̀ tó bọ́ sórí ilẹ̀ rere, ó sì so èso, òmíràn ọgọ́ọ̀rún, òmíràn ọgọ́tọ̀ọ̀ta, òmíràn ọgbọọgbọ̀n, ni ìlọ́po èyí ti ó gbìn. Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́.”

Read full chapter

(A)Nígbà tí ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, àwọn ènìyàn láti ìlú gbogbo sì tọ̀ ọ́ wá, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Afúnrúgbìn kan jáde lọ láti fún irúgbìn rẹ̀: bí ó sì ti ń fúnrúgbìn, díẹ̀ bọ́ sí ẹ̀bá ọ̀nà, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ṣà á jẹ. Òmíràn sì bọ́ sórí àpáta; bí ó sì ti hù jáde, ó gbẹ nítorí tí kò ní omi. Òmíràn sì bọ́ sínú ẹ̀gún; ẹ̀gún sì dàgbà pẹ̀lú rẹ̀ sókè, ó sì fún un pa. (B)Òmíràn sì bọ́ sí ilẹ̀ rere, ó sì hù sókè, ó sì so èso ọ̀rọ̀ọ̀rún ju èyí ti a gbin lọ.”

Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí tán, ó pariwo sókè pé, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́, kí ó gbọ́!”

Read full chapter