Matiu 13:16-17
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
16 (A)Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ojú yín, nítorí wọ́n ríran, àti fún etí yín, nítorí ti wọ́n gbọ́. 17 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti ènìyàn Ọlọ́run ti fẹ́ rí ohun tí ẹ̀yin ti rí, ki wọ́n sì gbọ́ ohun tí ẹ ti gbọ́, ṣùgbọ́n kò ṣe é ṣe fún wọn.
Read full chapter
Matthew 13:16-17
New International Version
16 But blessed are your eyes because they see, and your ears because they hear.(A) 17 For truly I tell you, many prophets and righteous people longed to see what you see(B) but did not see it, and to hear what you hear but did not hear it.
Johanu 8:56
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
56 (A)Abrahamu baba yín yọ̀ láti rí ọjọ́ mi: ó sì rí i, ó sì yọ̀.”
Read full chapter
John 8:56
New International Version
Heberu 11:13
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
13 (A)Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ó kú nínú ìgbàgbọ́, láìrí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, tí wọ́n sì gbá wọn mú, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àlejò àti àjèjì ni àwọn lórí ilẹ̀ ayé.
Read full chapter
Hebrews 11:13
New International Version
13 All these people were still living by faith when they died. They did not receive the things promised;(A) they only saw them and welcomed them from a distance,(B) admitting that they were foreigners and strangers on earth.(C)
1 Peteru 1:10-12
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn
10 Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wọ́n wádìí jinlẹ̀ lẹ́sọ̀ lẹ́sọ̀. 11 Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sá à wo ni Ẹ̀mí Kristi tí ó wà nínú wọ́n ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kristi àti ògo tí yóò tẹ̀lé e. 12 Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkára wọn, bí kò ṣe fún àwa ni wọ́n ṣe ìránṣẹ́ ohun wọ̀n-ọn-nì, tí a ti ròyìn fún yin nísinsin yìí, láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ti ń wàásù ìhìnrere náà fún yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run; ohun tí àwọn angẹli ń fẹ́ láti wò.
Read full chapter
1 Peter 1:10-12
New International Version
10 Concerning this salvation, the prophets, who spoke(A) of the grace that was to come to you,(B) searched intently and with the greatest care,(C) 11 trying to find out the time and circumstances to which the Spirit of Christ(D) in them was pointing when he predicted(E) the sufferings of the Messiah and the glories that would follow. 12 It was revealed to them that they were not serving themselves but you,(F) when they spoke of the things that have now been told you by those who have preached the gospel to you(G) by the Holy Spirit sent from heaven.(H) Even angels long to look into these things.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.
Holy Bible, New International Version®, NIV® Copyright ©1973, 1978, 1984, 2011 by Biblica, Inc.® Used by permission. All rights reserved worldwide.
NIV Reverse Interlinear Bible: English to Hebrew and English to Greek. Copyright © 2019 by Zondervan.