Add parallel Print Page Options

Òwe àwọn ayálégbé

33 (A)“Ẹ gbọ́ òwe mìíràn: Baálé ilé kan tí ó gbin ọgbà àjàrà, ó ṣe ọgbà yìí ká, ó wá ibi ìfúntí sínú rẹ̀, ó kọ́ ilé ìṣọ́. Ó sì fi oko náà ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn àgbẹ̀ kan, ó sì lọ sí ìrìnàjò. 34 Nígbà ti àkókò ìkórè súnmọ́, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sí àwọn àgbẹ̀ náà láti gba èyí ti ó jẹ tirẹ̀ wá.

35 “Ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọn lu ẹni kìn-ín-ní, wọn pa èkejì, wọ́n si sọ ẹ̀kẹta ní òkúta. 36 Ó sì tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn àwọn tí ó ju ti ìṣáájú lọ. Wọ́n sì túnṣe bí ti àkọ́kọ́ sí àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú. 37 Níkẹyìn, baálé ilé yìí rán ọmọ rẹ̀ pàápàá sí wọn. Ó wí pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ mi.’

38 “Ṣùgbọ́n bí àwọn alágbàtọ́jú wọ̀nyí ti rí ọmọ náà lókèèrè, wọ́n wí fún ara wọn pé, ‘Èyí ni àrólé náà. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí a sì jogún rẹ̀.’ 39 Wọ́n sì wọ́ ọ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà, wọ́n sì pa á.

40 “Ǹjẹ́ nígbà tí olúwa ọgbà àjàrà bá dé, kí ni yóò ṣe sí àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì?”

41 (B)Wọ́n wí pé, “Òun yóò pa àwọn ènìyàn búburú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú mìíràn tí yóò fún un ní èso tirẹ̀ lásìkò ìkórè.”

42 (C)Jesu wí fún wọ́n pé, “Àbí ẹ̀yin kò kà á nínú ìwé Mímọ́ pé:

“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
    ni ó di pàtàkì igun ilé;
iṣẹ́ Olúwa ni èyí,
    ó sì jẹ́ ìyanu ní ojú wa’?

43 “Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá. 44 Ẹni tí ó bá ṣubú lu òkúta yìí yóò di fífọ́, ṣùgbọ́n ẹni tí òun bá ṣubú lù yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”

45 Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi gbọ́ òwe Jesu, wọ́n mọ̀ wí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn. 46 Wọn wá ọ̀nà láti mú un, ṣùgbọ́n wọn bẹ̀rù ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n gba Jesu gẹ́gẹ́ bí wòlíì.

Read full chapter

Òwe àwọn ayálégbé

(A)(B) Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ sí í pa òwe yìí fún àwọn ènìyàn pé: “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan, ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí àjò fún ìgbà pípẹ́. 10 Nígbà tí ó sì tó àkókò, ó rán ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ kan sí àwọn olùṣọ́gbà náà: kí wọn lè fún un nínú èso ọgbà àjàrà náà: ṣùgbọ́n àwọn alágbàtọ́jú lù ú, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 11 Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn: wọ́n sì lù ú pẹ̀lú, wọ́n sì jẹ ẹ́ ní yà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. 12 Ó sì tún rán ẹ̀kẹta: wọ́n sì sá a lọ́gbẹ́ pẹ̀lú, wọ́n sì tì í jáde.

13 “Nígbà náà ni Olúwa ọgbà àjàrà wí pé, ‘Èwo ni èmi ó ṣe? Èmi ó rán ọmọ mi àyànfẹ́ lọ: bóyá nígbà tí wọ́n bá rí i, wọn yóò bu ọlá fún un.’

14 “Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn alágbàtọ́jú náà rí i, wọ́n bá ara wọn gbèrò pé, ‘Èyí ni àrólé; ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, kí ogún rẹ̀ lè jẹ́ ti wa.’ 15 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tì í jáde sẹ́yìn ọgbà àjàrà, wọ́n sì pa á.

“Ǹjẹ́ kín ni olúwa ọgbà àjàrà náà yóò ṣe sí wọn? 16 (C)Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.”

Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri i!”

17 (D)Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:

“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
    òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé’?

18 (E)Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá ṣubú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”

19 (F)Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà láti mú un ní wákàtí náà; ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù àwọn ènìyàn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé, ó pa òwe yìí mọ́ wọn.

Read full chapter

Orin ọgbà àjàrà náà

(A)Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn
    orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀;
Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan
    ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.
Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò
    ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i.
Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀
    ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú.
Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára,
    ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.

“Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu
    àti ẹ̀yin ènìyàn Juda
ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti
    ọgbà àjàrà mi.
Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi.
    Ju èyí tí mo ti ṣe lọ?
Nígbà tí mo ń wá èso dáradára,
    èéṣe tí ó fi so kíkan?
Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ
    ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi:
Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò,
    a ó sì pa á run,
Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀
    yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro
    láì kọ ọ́ láì ro ó,
ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.
    Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru
    láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”

Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    ni ilé Israẹli
àwọn ọkùnrin Juda
    sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.
Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí,
    Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.

Read full chapter