Add parallel Print Page Options

Ìgbéyàwó nígbà àjíǹde

23 (A)(B) Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan náà, àwọn Sadusi tí wọ́n sọ pé kò si àjíǹde lẹ́yìn ikú tọ Jesu wá láti bi í ní ìbéèrè, 24 (C)Wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mose wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un. 25 Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrín wa níhìn-ín yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje. Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú ní àìlọ́mọ. Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì. 26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ arákùnrin èkejì náà sì tún kú láìlọ́mọ. A sì fi ìyàwó rẹ̀ fún arákùnrin tí ó tún tẹ̀lé e. Bẹ́ẹ̀ sì ni títí tí òun fi di ìyàwó ẹni keje. 27 Níkẹyìn obìnrin náà pàápàá sì kú. 28 Nítorí tí ó ti ṣe ìyàwó àwọn arákùnrin méjèèje, ìyàwó ta ni yóò jẹ́ ní àjíǹde òkú?”

29 Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àìmọ̀kan yín ni ó fa irú ìbéèrè báyìí. Nítorí ẹ̀yin kò mọ ìwé Mímọ́ àti agbára Ọlọ́run. 30 Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó. Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn angẹli ní ọ̀run. 31 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nípa ti àjíǹde òkú, tàbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé Ọlọ́run ń bá yín sọ̀rọ̀ nígbà ti ó wí pé: 32 ‘Èmi ni Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run òkú, ṣùgbọ́n tí àwọn alààyè.”

33 (D)Nígbà ti àwọn ènìyàn gbọ́ èyí ẹnu yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ.

Read full chapter

Àjíǹde àti ìgbéyàwó

27 (A)(B) Àwọn Sadusi kan sì tọ̀ ọ́ wá, àwọn tí wọ́n ń wí pé àjíǹde òkú kò sí: wọ́n sì bi í, 28 (C)wí pé, “Olùkọ́, Mose kọ̀wé fún wa pé: Bí arákùnrin ẹnìkan bá kú, ní àìlọ́mọ, tí ó sì ní aya, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó lè gbé irú-ọmọ dìde fún arákùnrin rẹ̀. 29 Ǹjẹ́ àwọn arákùnrin méje kan ti wà; èkínní gbé ìyàwó, ó sì kú ní àìlọ́mọ. 30 Èkejì sì ṣú u lópó: òun sì kú ní àìlọ́mọ. 31 Ẹ̀kẹta sì ṣú u lópó: gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn méjèèje pẹ̀lú: wọn kò sì fi ọmọ sílẹ̀, wọ́n sì kú. 32 Nígbẹ̀yìn pátápátá obìnrin náà kú pẹ̀lú. 33 Ǹjẹ́ ní àjíǹde òkú, aya ti ta ni yóò ha ṣe nínú wọn? Nítorí àwọn méjèèje ni ó sá à ni í ní aya.”

34 Jesu sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Àwọn ọmọ ayé yìí a máa gbéyàwó, wọn a sì máa fa ìyàwó fún ni. 35 Ṣùgbọ́n àwọn tí a kà yẹ láti jogún ìyè ayérayé náà, àti àjíǹde kúrò nínú òkú, wọn kì í gbéyàwó, wọn kì í sì í fa ìyàwó fún ni. 36 Nítorí wọn kò lè kú mọ́; nítorí tí wọn bá àwọn angẹli dọ́gba; àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ni wọ́n, nítorí wọ́n di àwọn ọmọ àjíǹde. 37 (D)Ní ti pé a ń jí àwọn òkú dìde, Mose tìkára rẹ̀ sì ti fihàn nínú igbó, nígbà tí ó pe ‘Olúwa ni Ọlọ́run Abrahamu, àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu.’ 38 Bẹ́ẹ̀ ni òun kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, bí kò ṣe ti àwọn alààyè: nítorí gbogbo wọn wà láààyè fún un.”

Read full chapter