Add parallel Print Page Options

Òfin tí ó ga jùlọ

34 (A)Nígbà ti wọ́n sì gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusi lẹ́nu mọ́, àwọn Farisi pé ara wọn jọ. 35 (B)Ọ̀kan nínú wọn tí ṣe amòfin dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè yìí. 36 Ó wí pé, “Olùkọ́ èwo ni ó ga jùlọ nínú àwọn òfin?”

37 (C)Jesu dáhùn pé, “ ‘Fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, gbogbo ẹ̀mí rẹ àti gbogbo inú rẹ. 38 Èyí ni òfin àkọ́kọ́ àti èyí tí ó tóbi jùlọ. 39 Èkejì tí ó tún dàbí rẹ̀ ní pé, ‘Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’

Read full chapter

Òfin tí ó ga jùlọ

28 (A)Ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ òfin ti ó dúró níbẹ̀ tí ó sì fetísílẹ̀ dáradára sí àròyé yìí ṣàkíyèsí pé, Jesu ti dáhùn dáradára. Òun pẹ̀lú sì béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Nínú gbogbo òfin, èwo ló ṣe pàtàkì jùlọ?”

29 (B)Jesu dá ọkùnrin yìí lóhùn pé, “Èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwọn òfin ni èyí tí ó kà báyìí pé: ‘Gbọ́ Israẹli; Olúwa Ọlọ́run wa Olúwa kan ni. 30 Kí ìwọ kí ó fi gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo ẹ̀mí rẹ, àti gbogbo agbára rẹ fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, èyí ní òfin kìn-ín-ní.’ 31 (C)Èkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.”

Read full chapter