Add parallel Print Page Options

Ìdìtẹ̀ mọ́ Jesu

26 (A)Nígbà tí Jesu ti parí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé, (B)“Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé wọn lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”

Ní àsìkò tí Jesu ń sọ̀rọ̀ yìí, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà kó ara wọn jọ ní ààfin olórí àlùfáà náà tí à ń pè ní Kaiafa. Láti gbèrò àwọn ọ̀nà tí wọ́n yóò fi mú Jesu pẹ̀lú ẹ̀tàn, kí wọn sì pa á. Ṣùgbọ́n wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé, “Kì í ṣe lásìkò àsè àjọ ìrékọjá, nítorí rògbòdìyàn yóò ṣẹlẹ̀.”

Read full chapter

Judasi gbà láti da Jesu

22 (A)Àjọ ọdún àìwúkàrà tí à ń pè ní Ìrékọjá sì kù fẹ́ẹ́rẹ́. Àti àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé ń wá ọ̀nà tí wọn ìbá gbà pa á; nítorí tí wọn ń bẹ̀rù àwọn ènìyàn.

Read full chapter

47 Nígbà náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi pe ìgbìmọ̀ jọ.

Wọ́n sì wí pé, “Kín ni yóò jẹ àṣeyọrí wa? Nítorí ọkùnrin yìí ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ààmì. 48 Bí àwa bá fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀, gbogbo ènìyàn ni yóò gbà á gbọ́: àwọn ará Romu yóò sì wá gba ilẹ̀ àti orílẹ̀-èdè wa pẹ̀lú.”

49 (A)Ṣùgbọ́n Kaiafa, ọ̀kan nínú wọn, ẹni tí í ṣe olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohunkóhun rárá! 50 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ronú pé, ó ṣàǹfààní fún wa, kí ènìyàn kan kú fún àwọn ènìyàn kí gbogbo orílẹ̀-èdè má ba à ṣègbé.”

51 Kì í ṣe fún ara rẹ̀ ni ó sọ èyí ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ olórí àlùfáà ní ọdún náà, ó sọtẹ́lẹ̀ pé, Jesu yóò kú fún orílẹ̀-èdè náà: 52 (B)Kì sì í ṣe kìkì fún orílẹ̀-èdè náà nìkan, ṣùgbọ́n fún àwọn ọmọ Ọlọ́run tí ó fọ́nká kiri, kí ó le kó wọn papọ̀, kí ó sì sọ wọ́n di ọ̀kan. 53 Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á.

Read full chapter