Add parallel Print Page Options

63 (A)Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́ rọ́rọ́.

Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè: Kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kristi Ọmọ Ọlọ́run.”

64 (B)Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.”

65 (C)Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tìkára rẹ̀ ya. Ó sì kígbe pé, “Ọ̀rọ̀-òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì rẹ̀. Kí ni ìdájọ́ yín?” 66 Ki ni ẹ ti rò èyí sí.

Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, “Ó jẹ̀bi ikú!”

Read full chapter

61 Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́.

Olórí àlùfáà tún bi í, lẹ́ẹ̀kan sí i, ó ní, “Ṣé ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún un nì?”

62 (A)Jesu wá dáhùn, ó ni, “Èmi ni: Ẹ̀yin yóò sì rí Ọmọ Ènìyàn tí yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún agbára. Ẹ̀yin yóò sì tún rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ń bọ̀ láti inú àwọsánmọ̀ ojú ọ̀run.”

63 (B)Nígbà náà ni Olórí àlùfáà fa aṣọ rẹ̀ ya, ó ní, “Kí ló kù tì a ń wá? Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? 64 (C)Ẹ̀yin fúnrayín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì tí ó sọ. Kí ni ẹ rò pé ó tọ́ kí a ṣe?”

Gbogbo wọ́n sì dáhùn wí pé, “Ó jẹ̀bi ikú.”

Read full chapter

Alábojútó àlùfáà fi ọ̀rọ̀ wá Jesu lẹ́nu wò

19 (A)Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jesu léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀.

20 Jesu dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sinagọgu, àti ní tẹmpili níbi tí gbogbo àwọn Júù ń péjọ sí: èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀. 21 Èéṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo wí fún wọn: wò ó, àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí èmi wí.”

Read full chapter