Add parallel Print Page Options

Peteru sẹ́ Jesu

69 Lákòókò yìí, bí Peteru ti ń jókòó ní àgbàlá, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Ìwọ wà pẹ̀lú Jesu ti Galili.”

70 Ṣùgbọ́n Peteru sẹ̀ ní ojú gbogbo wọn pé “Èmi kò tilẹ̀ mọ ohun tí ẹ ń sọ nípa rẹ̀.”

71 Lẹ́yìn èyí, ní ìta ní ẹnu-ọ̀nà, ọmọbìnrin mìíràn tún rí i, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró yíká pé, “Ọkùnrin yìí wà pẹ̀lú Jesu ti Nasareti.”

72 Peteru sì tún sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì pẹ̀lú ìbúra pé, “Èmi kò tilẹ̀ mọ ọkùnrin náà rárá.”

73 Nígbà tí ó pẹ́ díẹ̀, àwọn ọkùnrin tí ó ń dúró níbi ìran yìí tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún Peteru pé, “Lóòótọ́, ìwọ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, àwa mọ̀ ọ́n. Èyí sì dá wa lójú nípa ààmì ohùn rẹ̀ tí ó ń ti ẹnu rẹ jáde.”

74 Peteru sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í búra ó sì fi ara rẹ̀ ré wí pé, “Mo ní èmi kò mọ ọkùnrin yìí rárá.”

Lójúkan náà àkùkọ sì kọ. 75 (A)Nígbà náà ni Peteru rántí nǹkan tí Jesu ti sọ pé, “Kí àkùkọ tó ó kọ, ìwọ yóò sẹ́ mi nígbà mẹ́ta.” Òun sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

Read full chapter

56 (A)Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”

57 Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”

58 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”

Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.”

59 Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.”

60 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ! 61 (B)Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.” 62 Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

Read full chapter

16 Ṣùgbọ́n Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùṣọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Peteru wọlé.

17 (A)Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà wí fún Peteru pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?”

Ó wí pé, “Èmi kọ́.”

18 Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn aláṣẹ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí ti òtútù mú, wọ́n sì ń yáná: Peteru sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.

Read full chapter

Peteru sẹ́ Jesu ní ìgbà kejì àti ìgbà kẹta

25 (A)Ṣùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?”

Ó sì sẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.”

26 Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Peteru gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?” 27 Peteru tún sẹ́: lójúkan náà àkùkọ sì kọ.

Read full chapter

30 (A)Jesu si wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tó ó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ́ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”

Read full chapter