Add parallel Print Page Options

Pípe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àkọ́kọ́

18 (A)Bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, ó rí àwọn arákùnrin méjì, Simoni, ti à ń pè ní Peteru, àti Anderu arákùnrin rẹ̀. Wọ́n ń sọ àwọ̀n wọn sínú Òkun nítorí apẹja ni wọ́n. 19 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá, ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 20 Lójúkan náà, wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

21 Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú Sebede baba wọn, wọ́n ń di àwọ̀n wọn, Jesu sì pè àwọn náà pẹ̀lú. 22 Lójúkan náà, wọ́n fi ọkọ̀ ojú omi àti baba wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Read full chapter

16 (A)Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń rìn létí Òkun Galili, Ó rí Simoni àti Anderu arákùnrin rẹ̀, wọ́n ń fi àwọ̀n wọn pẹja torí pé apẹja ni wọ́n. 17 Jesu sì ké sí wọn wí pé, “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn. Èmi yóò sì sọ yín di apẹja ènìyàn.” 18 Ní kánkán wọ́n fi àwọ̀n wọn sílẹ̀, wọ́n sì tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn.

19 Bí Ó sì ti rìn síwájú díẹ̀, ní etí Òkun, Ó rí Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ nínú ọkọ̀, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. 20 Ó sì ké sí àwọn náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n fi Sebede baba wọn sílẹ̀ nínú ọkọ̀ pẹ̀lú àwọn alágbàṣe, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

Read full chapter

40 (A)Anderu arákùnrin Simoni Peteru jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méjì tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó sì tọ Jesu lẹ́yìn. 41 (B)Ohun àkọ́kọ́ tí Anderu ṣe ni láti wá Simoni arákùnrin rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Àwa ti rí Messia” (ẹni tí ṣe Kristi). 42 (C)Ó sì mú un wá sọ́dọ̀ Jesu.

Jesu sì wò ó, ó wí pé, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Jona: Kefa ni a ó sì máa pè ọ” (ìtumọ̀ èyí tí ṣe Peteru).

Read full chapter

Jesu àti iṣẹ́ ìyanu ẹja pípa

21 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu tún fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ létí Òkun Tiberia; báyìí ni ó sì farahàn. (A)Simoni Peteru, àti Tomasi tí a ń pè ní Didimu, àti Natanaeli ará Kana ti Galili, àti àwọn ọmọ Sebede, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjì mìíràn jùmọ̀ wà pọ̀. (B)Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.

(C)Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mọ́, Jesu dúró létí Òkun: ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni.

(D)Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní ẹja díẹ̀ bí?”

Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o.”

Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ sọ àwọ̀n sí apá ọ̀tún ọkọ̀ ojú omi, ẹ̀yin yóò sì rí.” Nígbà tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè fà á jáde nítorí ọ̀pọ̀ ẹja.

(E)Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jesu fẹ́ràn wí fún Peteru pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú Òkun. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù mú ọkọ̀ ojú omi kékeré kan wá nítorí tí wọn kò jìnà sílẹ̀, ṣùgbọ́n bí ìwọ̀n igba ìgbọ̀nwọ́; wọ́n ń wọ́ àwọ̀n náà tí ó kún fún ẹja. Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹ̀yín iná níbẹ̀ àti ẹja lórí rẹ̀ àti àkàrà.

10 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú nínú ẹja tí ẹ pa nísinsin yìí wá.” 11 Nítorí náà, Simoni Peteru gòkè, ó sì fa àwọ̀n náà wálẹ̀, ó kún fún ẹja ńlá, ó jẹ́ mẹ́tàléláádọ́jọ: bí wọ́n sì ti pọ̀ tó náà, àwọ̀n náà kò ya. 12 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun òwúrọ̀.” Kò sì sí ẹnìkan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó jẹ́ bí i pé, “Ta ni ìwọ ṣe?” Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Olúwa ni. 13 Jesu wá, ó sì mú àkàrà, ó sì fi fún wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹja. 14 (F)Èyí ni Ìgbà kẹta nísinsin yìí tí Jesu farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú.

Jesu fún Peteru ní iṣẹ́

15 (G)Ǹjẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹun òwúrọ̀ tan, Jesu wí fún Simoni Peteru pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?”

Ó sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”

Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

16 (H)Ó tún wí fún un nígbà kejì pé, “Simoni ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ mi bí?”

Ó wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”

Ó wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi.”

17 Ó wí fún un nígbà kẹta pé, “Simoni, ọmọ Jona, ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?”

Inú Peteru sì bàjẹ́, nítorí tí ó wí fún un nígbà ẹ̀kẹta pé, “Ìwọ fẹ́ràn mi nítòótọ́ bí?” Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé, mo fẹ́ràn rẹ.”

Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi. 18 Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún ọ, nígbà tí ìwọ wà ní ọ̀dọ́mọdé, ìwọ a máa di ara rẹ ní àmùrè, ìwọ a sì máa rìn lọ sí ibi tí ìwọ bá fẹ́: ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá di arúgbó, ìwọ yóò na ọwọ́ rẹ jáde, ẹlòmíràn yóò sì dì ọ́ ní àmùrè, yóò mú ọ lọ sí ibi tí ìwọ kò fẹ́.” 19 (I)Jesu wí èyí, ó fi ń ṣe àpẹẹrẹ irú ikú tí yóò fi yin Ọlọ́run lógo. Lẹ́yìn ìgbà tí ó sì ti wí èyí tan, ó wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

Read full chapter