Add parallel Print Page Options

Ìwọ ìbá rí bí arákùnrin mi si mi,
    èyí tí ó mú ọmú ìyá mi dàgbà!
Èmi ìbá rí ọ ní òde,
    èmi ìbá fi ẹnu kò ọ́ ní ẹnu,
    wọn kì bá fi mí ṣe ẹlẹ́yà.
Èmi ìbá fi ọ̀nà hàn ọ́
    èmi ìbá mú ọ wá sínú ilé ìyá
    mi, ìwọ ìbá kọ́ mi
èmi ìbá fi ọtí wáìnì olóòórùn dídùn fún ọ mu
    àti oje èso pomegiranate mi.
Ọwọ́ òsì rẹ ìbá wà ní abẹ́ orí mi,
    ọwọ́ ọ̀tún rẹ ìbá sì gbà mí mọ́ra.
Ọmọbìnrin Jerusalẹmu, èmi pè yín ní ìjà,
    Ẹ má ṣe rú olùfẹ́ mi sókè,
    Ẹ má ṣe jí i títí tí yóò fi wù ú.

Ọ̀rẹ́

Ta ni ẹni tí ń gòkè bọ̀ wá láti aginjù,
    tí ó fi ara ti olùfẹ́ rẹ̀.

Olólùfẹ́

Ní abẹ́ igi ápù ni mo ti jí ọ dìde; níbẹ̀ ni ìyá rẹ ti lóyún rẹ
    níbẹ̀ ni ẹni tí ń rọbí bí ọ sí.
Gbé mi sí àyà rẹ bí èdìdì
    bí èdìdì lé apá rẹ;
nítorí ìfẹ́ lágbára bí ikú,
    ìjowú sì le bí isà òkú
jíjò rẹ̀ rí bí jíjò iná,
    gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́-iná Olúwa.
Omi púpọ̀ kò le paná ìfẹ́;
    bẹ́ẹ̀ ni gbígbá omi kò le gbá a lọ.
Bí ènìyàn bá fún ìfẹ́,
    ní gbogbo ọrọ̀ ilé rẹ̀,
    a ó kẹ́gàn rẹ̀ pátápátá.

Ọ̀rẹ́

Àwa ní arábìnrin kékeré kan,
    òun kò sì ní ọmú,
kí ni àwa yóò fún arábìnrin wa,
    ní ọjọ́ tí a ó bá fẹ́ ẹ?
Bí òun bá jẹ́ ògiri,
    àwa yóò kọ́ ilé odi fàdákà lé e lórí.
Bí òun bá jẹ́ ìlẹ̀kùn,
    Àwa yóò fi pákó kedari dí i.

Olólùfẹ́

10 Èmi jẹ́ ògiri,
    ọmú mi sì rí bí ilé ìṣọ́
bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe rí ní ojú rẹ̀
    bí ẹni tí ń mú àlàáfíà wá.
11 Solomoni ní ọgbà àjàrà kan ní Baali-Hamoni
    ó gbé ọgbà àjàrà rẹ̀ fún àwọn alágbàtọ́jú
olúkúlùkù ni ó ń mú èso rẹ̀ wá
    ẹgbẹ̀rún fàdákà.
12 Ṣùgbọ́n ọgbà àjàrà mi jẹ́ tèmi, ó wà fún mi;
    ẹgbẹ̀rún ṣékélì jẹ́ tìrẹ, ìwọ Solomoni,
    igba sì jẹ́ ti àwọn alágbàtọ́jú èso.

Olólùfẹ́

13 Ìwọ tí ń gbé inú ọgbà,
    àwọn ọ̀rẹ́ rẹ dẹtí sí ohùn rẹ,
    jẹ́ kí èmi náà gbọ́ ohùn rẹ!

Olólùfẹ́

14 Yára wá, Olùfẹ́ mi,
    kí ìwọ kí ó sì rí bí abo egbin,
tàbí gẹ́gẹ́ bí ọmọ àgbọ̀nrín,
    lórí òkè òórùn dídùn.