Add parallel Print Page Options

15 (A)Bí inú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí oúnjẹ rẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má ṣe fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kristi kú fún di ẹni ègbé.

Read full chapter

(A)Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsi ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má ba à mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í ṣe onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. 10 Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti ìwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, láti jẹ oúnjẹ tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà? 11 (B)Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kristi kú fún. 12 (C)Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arákùnrin rẹ̀ tí ẹ sì ń pa ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́ṣẹ̀ sí Kristi jùlọ.

Read full chapter