Add parallel Print Page Options

111 Ẹ máa yin Olúwa.

Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
    ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.

Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
    àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
    Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
    òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.

Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
    láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
    gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
Wọ́n dúró láé àti láé,
    ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
    ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé:
    Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.

10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
    òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
    ìyìn rẹ̀ dúró láé.