Add parallel Print Page Options

Fún adarí orin. Tí ohun orin “Lílì.” Ti orin àwọn ọmọ Kora. Maskili. Orin ìgbéyàwó.

45 Ọkàn mi mọ ọ̀rọ̀ rere
    gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń sọ ohun tí mo ti ṣe fún ọba
    ahọ́n mi ni kálámù ayára kọ̀wé.

Ìwọ yanjú ju àwọn ọmọ ènìyàn lọ:
    a da oore-ọ̀fẹ́ sí ọ ní ètè:
    nítorí náà ni Ọlọ́run ṣe bùkún fún ọ láéláé.

Gba idà rẹ mọ́ ìhà rẹ, ìwọ alágbára jùlọ
    wọ ara rẹ ní ògo àti ọláńlá.
Nínú ọláńlá rẹ, máa gẹṣin lọ ní àlàáfíà
    lórí òtítọ́, ìwà tútù àti òtítọ́
    jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ohun ẹ̀rù.
Jẹ́ kí ọfà mímú rẹ̀ dá ọkàn àwọn ọ̀tá ọba lu
    jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.
(A)Ọlọ́run láé, àti láéláé ni ìtẹ́ rẹ,
    ọ̀pá aládé ìjọba rẹ, ọ̀pá aládé òtítọ́ ni.
Ìwọ fẹ́ olódodo, ìwọ sì kórìíra ìwà búburú
    nígbà náà Ọlọ́run, Ọlọ́run rẹ ti yàn ọ́ ṣe olórí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ,
    nípa fífi ààmì òróró ayọ̀ kùn ọ́.
Gbogbo aṣọ rẹ̀ ni ó ń rùn pẹ̀lú òjìá àti aloe àti kasia;
    láti inú ààfin tí a fi eyín erin ṣe
    orin olókùn tẹ́ẹ́rẹ́ mú inú rẹ̀ dùn.
Àwọn ọmọbìnrin àwọn ọba
    wà nínú àwọn àyànfẹ́ rẹ̀,
ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ayaba náà gbé dúró
    nínú wúrà ofiri.

10 Gbọ́ ìwọ ọmọbìnrin, ronú kí o sì dẹtí rẹ sí mi
    gbàgbé àwọn ènìyàn rẹ àti ilé baba rẹ
11 Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà rẹ gidigidi
    nítorí òun ni olúwa rẹ
kí ìwọ sì máa tẹríba fún un.
12 Ọmọbìnrin ọba Tire yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùn
    àwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojúrere rẹ̀.
13 Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárín ilé rẹ̀,
    iṣẹ́ wúrà ọnà abẹ́rẹ́ ní aṣọ rẹ̀.
14 Nínú aṣọ olówó iyebíye ni a mú un tọ́ ọba wá,
    àwọn wúńdíá ẹgbẹ́ rẹ̀ tẹ̀lé e, wọ́n sí mú un tọ̀ ọ́ wá.
15 Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùn
    wọ́n sì wọ ààfin ọba.

16 Ọmọ rẹ̀ ni yóò gba ipò baba rẹ̀
    ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.

17 Èmí yóò máa rántí orúkọ rẹ̀ ní ìran gbogbo,
    nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.