Add parallel Print Page Options

(A)Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.”
    Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?”

“Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko,
    àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó.
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
    nítorí èémí Olúwa ń fẹ́ lù wọ́n.
    Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn.
Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀,
    ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.”

(B)Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni,
    lọ sí orí òkè gíga.
Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu,
    gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo,
gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù;
    sọ fún àwọn ìlú u Juda,
    “Ọlọ́run rẹ nìyìí!”

Read full chapter