Add parallel Print Page Options

Jeremiah àti Paṣuri

20 Ní ìgbà tí àlùfáà Paṣuri ọmọkùnrin Immeri olórí àwọn ìjòyè tẹmpili Olúwa gbọ́ tí Jeremiah ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí. Ó mú kí wọ́n lù wòlíì Jeremiah, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu-ọ̀nà ti Benjamini ní tẹmpili Olúwa. (A)Ní ọjọ́ kejì tí Paṣuri tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremiah sì sọ fún un wí pé, “orúkọ Olúwa fun ọ kì í ṣe Paṣuri bí kò ṣe ìpayà. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Juda lé ọba Babeli lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Babeli tàbí kí ó pa wọ́n. Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀tá wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá ọba Juda. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Babeli. Àti ìwọ Paṣuri, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Babeli. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.”

Ìráhùn Jeremiah

Olúwa, o tàn mí jẹ́,
    o sì ṣẹ́gun.
Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́,
    gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.
Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta
    èmi á sọ nípa ipá àti ìparun.
Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù
    àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.
Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ
    tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi
    nínú egungun mi
Agara dá mi ní inú mi
    nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.
10 Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,
    ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo
Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn!
    Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró
kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé,
    Bóyá yóò jẹ́ di títàn,
nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀,
    àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”

11 Ṣùgbọ́n Olúwa ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù.
    Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀,
wọn kì yóò sì borí.
    Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀.
    Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.
12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò
    tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀mí fínní fínní,
jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn,
    nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.

13 Kọrin sí Olúwa!
    Fi ìyìn fún Olúwa!
Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní
    lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.

14 Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi!
    Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.
15 Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi,
    Tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé,
    “A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!”
16 Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú
    Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú
Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀,
    ariwo ogun ní ọ̀sán.
17 Nítorí kò pa mí nínú,
    kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi,
    kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé.
18 Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn,
    láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀
    àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?

Jeremiah and Pashhur

20 When the priest Pashhur son of Immer,(A) the official(B) in charge of the temple of the Lord, heard Jeremiah prophesying these things, he had Jeremiah the prophet beaten(C) and put in the stocks(D) at the Upper Gate of Benjamin(E) at the Lord’s temple. The next day, when Pashhur released him from the stocks, Jeremiah said to him, “The Lord’s name(F) for you is not Pashhur, but Terror on Every Side.(G) For this is what the Lord says: ‘I will make you a terror to yourself and to all your friends; with your own eyes(H) you will see them fall by the sword of their enemies. I will give(I) all Judah into the hands of the king of Babylon, who will carry(J) them away to Babylon or put them to the sword. I will deliver all the wealth(K) of this city into the hands of their enemies—all its products, all its valuables and all the treasures of the kings of Judah. They will take it away(L) as plunder and carry it off to Babylon. And you, Pashhur, and all who live in your house will go into exile to Babylon. There you will die and be buried, you and all your friends to whom you have prophesied(M) lies.’”

Jeremiah’s Complaint

You deceived[a](N) me, Lord, and I was deceived[b];
    you overpowered(O) me and prevailed.
I am ridiculed(P) all day long;
    everyone mocks(Q) me.
Whenever I speak, I cry out
    proclaiming violence and destruction.(R)
So the word of the Lord has brought me
    insult and reproach(S) all day long.
But if I say, “I will not mention his word
    or speak anymore in his name,”(T)
his word is in my heart like a fire,(U)
    a fire shut up in my bones.
I am weary of holding it in;(V)
    indeed, I cannot.
10 I hear many whispering,
    “Terror(W) on every side!
    Denounce(X) him! Let’s denounce him!”
All my friends(Y)
    are waiting for me to slip,(Z) saying,
“Perhaps he will be deceived;
    then we will prevail(AA) over him
    and take our revenge(AB) on him.”

11 But the Lord(AC) is with me like a mighty warrior;
    so my persecutors(AD) will stumble and not prevail.(AE)
They will fail and be thoroughly disgraced;(AF)
    their dishonor will never be forgotten.
12 Lord Almighty, you who examine the righteous
    and probe the heart and mind,(AG)
let me see your vengeance(AH) on them,
    for to you I have committed(AI) my cause.

13 Sing(AJ) to the Lord!
    Give praise to the Lord!
He rescues(AK) the life of the needy
    from the hands of the wicked.(AL)

14 Cursed be the day I was born!(AM)
    May the day my mother bore me not be blessed!
15 Cursed be the man who brought my father the news,
    who made him very glad, saying,
    “A child is born to you—a son!”
16 May that man be like the towns(AN)
    the Lord overthrew without pity.
May he hear wailing(AO) in the morning,
    a battle cry at noon.
17 For he did not kill me in the womb,(AP)
    with my mother as my grave,
    her womb enlarged forever.
18 Why did I ever come out of the womb(AQ)
    to see trouble(AR) and sorrow
    and to end my days in shame?(AS)

Footnotes

  1. Jeremiah 20:7 Or persuaded
  2. Jeremiah 20:7 Or persuaded