Add parallel Print Page Options

15 Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má sì ṣe ohun tí ó wu ara wa. Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró. (A)Nítorí Kristi pàápàá kò ṣe ohun tí ó wu ara rẹ̀, ṣùgbọ́n, bí a ti kọ ọ́ pé: “Ẹ̀gàn àwọn ẹni tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mi.” (B)Nítorí ohun gbogbo tí a kọ tẹ́lẹ̀, ni a kọ láti fi kọ́ wa pé, nípa sùúrù àti ìtùnú ìwé mímọ́, kí àwa lè ní ìrètí.

(C)Kí Ọlọ́run, ẹni tí ń fún ni ní sùúrù àti ìtùnú fún yin láti ní inú kan sí ara yín gẹ́gẹ́ bí i Jesu Kristi, kí ẹ̀yin kí ó lè fi ọkàn kan àti ẹnu kan fi ògo fún Ọlọ́run, Baba Olúwa wa Jesu Kristi.

Nítorí náà ẹ gba ara yín mọ́ra, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti gbà wá mọ́ra fún ògo Ọlọ́run. Mo sì wí pé, a rán Kristi láti ṣe ìránṣẹ́ ìkọlà àwọn tí ṣe Júù nítorí òtítọ́ Ọlọ́run, láti fi ìdí àwọn ìlérí tí a ti ṣe fún àwọn baba múlẹ̀, (D)kí àwọn aláìkọlà kí ó lè yin Ọlọ́run lógo nítorí àánú rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Nítorí èyí ni èmi ó ṣe yìn ọ́ láàrín àwọn Kèfèrí,
    Èmi ó sì kọrin sí orúkọ rẹ.”

10 (E)Ó sì tún wí pé,

“Ẹ̀yin Kèfèrí, ẹ ma yọ̀, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.”

11 (F)Àti pẹ̀lú,

“Ẹyin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin Kèfèrí;
    ẹ kọ orin ìyìn sí, ẹ̀yin ènìyàn gbogbo.”

12 (G)Isaiah sì tún wí pé,

“Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá,
    òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí;
Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”

13 Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yin ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrètí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.

Paulu wàásù sí àwọn Kèfèrí

14 Ẹ̀yin ará, èmi gan alára ti ní ìdánilójú, pé ẹ̀yin pàápàá kún fún oore, a sì fi gbogbo ìmọ̀ kún un yín, ẹ̀yin sì jáfáfá láti máa kọ́ ara yín. 15 Síbẹ̀ mo ti fi ìgboyà kọ̀wé sí yín lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ kan, bí ẹni ti ń rán yín létí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ náà, nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí a ti fi fún mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run 16 (H)láti jẹ́ ìránṣẹ́ Kristi Jesu láàrín àwọn Kèfèrí láti polongo ìhìnrere Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ojúṣe àlùfáà, kí àwọn Kèfèrí lè jẹ́ ẹbọ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run, èyí tí a ti fi Ẹ̀mí mímọ́ yà sí mímọ́.

17 Nítorí náà, mo ní ìṣògo nínú Kristi Jesu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi fún Ọlọ́run. 18 (I)Èmi kò sá à gbọdọ̀ sọ ohun kan bí kò ṣe èyí tí Kristi ti ọwọ́ mi ṣe, ní títọ́ àwọn Kèfèrí ṣọ́nà láti ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nípa ọ̀rọ̀ àti ìṣe mi: 19 (J)nípa agbára iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu, nípa agbára Ẹ̀mí Ọlọ́run, tó bẹ́ẹ̀ láti Jerusalẹmu àti yíkákiri, àní títí fi dé Illirikoni, mo ti polongo ìhìnrere Kristi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. 20 (K)Ó jẹ́ èrò mi ní gbogbo ìgbà láti wàásù ìhìnrere Kristi ní ibi gbogbo tí wọn kò tí ì mọ̀ ọ́n, kí èmi kí ó má ṣe máa mọ àmọlé lórí ìpìlẹ̀ ẹlòmíràn. 21 (L)Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Àwọn ẹni tí a kò tí ì sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún yóò rí i,
    àti àwọn tí kò tí ì gbọ́, òye yóò sì yé.”

22 (M)Ìdí nìyìí tí ààyè fi há pẹ́ tó bẹ́ẹ̀ fún mi kí n tó tọ̀ yín wa.

Paulu ṣètò láti ṣé àbẹ̀wò sí Romu

23 (N)Ṣùgbọ́n báyìí tí kò tún sí ibòmíràn fún mi mọ́ láti ṣiṣẹ́ ní ẹkùn yìí, tí èmi sì ti ń pòǹgbẹ láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn láti bẹ́ yín wò, 24 (O)mo gbèrò láti ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí mo bá lọ sí Spania. Èmi yóò rí i yín ní ọ̀nà àjò mi, àti pé ẹ ó mú mi já ọ̀nà níbẹ̀ láti ọ̀dọ̀ yín lọ, lẹ́yìn tí mo bá gbádùn ẹgbẹ́ yín fún ìgbà díẹ̀. 25 (P)Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ń lọ sí Jerusalẹmu láti sé ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀. 26 (Q)Nítorí pé ó wu àwọn tí ó wà ní Makedonia àti Akaia láti kó owó jọ fún àwọn tálákà tí ó wà ní àárín àwọn ènìyàn mímọ́ ní Jerusalẹmu. 27 (R)Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń ṣe èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbèsè fún wọn. Nítorí bí ó bá ṣe pé a fi àwọn Kèfèrí ṣe alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ. 28 (S)Nítorí náà, nígbà tí mo bá ti ṣe èyí tán, tí mo bá sì di èdìdì èso náà fún wọn tán, èmi yóò ti ọ̀dọ̀ yín lọ sí Spania. 29 (T)Mo sì mọ̀ pé nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, èmi yóò wà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkún ìhìnrere Kristi.

30 Èmí rọ̀ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, nítorí Olúwa wa Jesu Kristi, àti nítorí ìfẹ́ Ẹ̀mí, kí ẹ̀yin kí ó kún mi láti bá mi làkàkà nínú àdúrà yín sí Ọlọ́run fún mi. 31 (U)Kí a lè kó mi yọ kúrò lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́ ní Judea àti kí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí mo ní sí Jerusalẹmu le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀, 32 (V)kí èmi le fi ayọ̀ tọ̀ yín wa, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, àti kí èmi lè ní ìtura pọ̀ pẹ̀lú yín. 33 (W)Kí Ọlọ́run àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.

15 We who are strong ought to bear with the failings of the weak(A) and not to please ourselves. Each of us should please our neighbors for their good,(B) to build them up.(C) For even Christ did not please himself(D) but, as it is written: “The insults of those who insult you have fallen on me.”[a](E) For everything that was written in the past was written to teach us,(F) so that through the endurance taught in the Scriptures and the encouragement they provide we might have hope.

May the God who gives endurance and encouragement give you the same attitude of mind(G) toward each other that Christ Jesus had, so that with one mind and one voice you may glorify(H) the God and Father(I) of our Lord Jesus Christ.

Accept one another,(J) then, just as Christ accepted you, in order to bring praise to God. For I tell you that Christ has become a servant of the Jews[b](K) on behalf of God’s truth, so that the promises(L) made to the patriarchs might be confirmed and, moreover, that the Gentiles(M) might glorify God(N) for his mercy. As it is written:

“Therefore I will praise you among the Gentiles;
    I will sing the praises of your name.”[c](O)

10 Again, it says,

“Rejoice, you Gentiles, with his people.”[d](P)

11 And again,

“Praise the Lord, all you Gentiles;
    let all the peoples extol him.”[e](Q)

12 And again, Isaiah says,

“The Root of Jesse(R) will spring up,
    one who will arise to rule over the nations;
    in him the Gentiles will hope.”[f](S)

13 May the God of hope fill you with all joy and peace(T) as you trust in him, so that you may overflow with hope by the power of the Holy Spirit.(U)

Paul the Minister to the Gentiles

14 I myself am convinced, my brothers and sisters, that you yourselves are full of goodness,(V) filled with knowledge(W) and competent to instruct one another. 15 Yet I have written you quite boldly on some points to remind you of them again, because of the grace God gave me(X) 16 to be a minister of Christ Jesus to the Gentiles.(Y) He gave me the priestly duty of proclaiming the gospel of God,(Z) so that the Gentiles might become an offering(AA) acceptable to God, sanctified by the Holy Spirit.

17 Therefore I glory in Christ Jesus(AB) in my service to God.(AC) 18 I will not venture to speak of anything except what Christ has accomplished through me in leading the Gentiles(AD) to obey God(AE) by what I have said and done— 19 by the power of signs and wonders,(AF) through the power of the Spirit of God.(AG) So from Jerusalem(AH) all the way around to Illyricum, I have fully proclaimed the gospel of Christ.(AI) 20 It has always been my ambition to preach the gospel(AJ) where Christ was not known, so that I would not be building on someone else’s foundation.(AK) 21 Rather, as it is written:

“Those who were not told about him will see,
    and those who have not heard will understand.”[g](AL)

22 This is why I have often been hindered from coming to you.(AM)

Paul’s Plan to Visit Rome

23 But now that there is no more place for me to work in these regions, and since I have been longing for many years to visit you,(AN) 24 I plan to do so when I go to Spain.(AO) I hope to see you while passing through and to have you assist(AP) me on my journey there, after I have enjoyed your company for a while. 25 Now, however, I am on my way to Jerusalem(AQ) in the service(AR) of the Lord’s people(AS) there. 26 For Macedonia(AT) and Achaia(AU) were pleased to make a contribution for the poor among the Lord’s people in Jerusalem.(AV) 27 They were pleased to do it, and indeed they owe it to them. For if the Gentiles have shared in the Jews’ spiritual blessings, they owe it to the Jews to share with them their material blessings.(AW) 28 So after I have completed this task and have made sure that they have received this contribution, I will go to Spain(AX) and visit you on the way. 29 I know that when I come to you,(AY) I will come in the full measure of the blessing of Christ.

30 I urge you, brothers and sisters, by our Lord Jesus Christ and by the love of the Spirit,(AZ) to join me in my struggle by praying to God for me.(BA) 31 Pray that I may be kept safe(BB) from the unbelievers in Judea and that the contribution(BC) I take to Jerusalem may be favorably received by the Lord’s people(BD) there, 32 so that I may come to you(BE) with joy, by God’s will,(BF) and in your company be refreshed.(BG) 33 The God of peace(BH) be with you all. Amen.

Footnotes

  1. Romans 15:3 Psalm 69:9
  2. Romans 15:8 Greek circumcision
  3. Romans 15:9 2 Samuel 22:50; Psalm 18:49
  4. Romans 15:10 Deut. 32:43
  5. Romans 15:11 Psalm 117:1
  6. Romans 15:12 Isaiah 11:10 (see Septuagint)
  7. Romans 15:21 Isaiah 52:15 (see Septuagint)